1. NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa.
2. Awọn olori gbogbo enia na, ani ti gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, si pésẹ̀ larin ijọ awọn enia Ọlọrun, ogún ọkẹ ọkunrin ẹlẹsẹ̀ ti o kọ idà.
3. (Awọn ọmọ Benjamini si gbọ́ pe awọn ọmọ Israeli gòke lọ si Mispa.) Awọn ọmọ Israeli si wipe, Sọ fun wa, bawo ni ti ìwabuburu yi ti ri?