A. Oni 2:4-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O si ṣe, nigbati angeli OLUWA sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.

5. Nwọn si pè orukọ ibẹ̀ na ni Bokimu: nwọn si ru ẹbọ nibẹ̀ si OLUWA.

6. Nigbati Joṣua si ti jọwọ awọn enia lọwọ lọ, olukuluku awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ilẹ-iní rẹ̀ lati gba ilẹ̀ na.

7. Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, awọn ẹniti o ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli.

8. Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA si kú, nigbati o di ẹni ãdọfa ọdún.

9. Nwọn si sinkú rẹ̀ li àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnati-heresi, ni ilẹ òke Efraimu, li ariwa oke Gaaṣi.

10. Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli.

11. Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu:

12. Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu.

13. Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu.

14. Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn.

15. Nibikibi ti nwọn ba jade lọ, ọwọ́ OLUWA wà lara wọn fun buburu, gẹgẹ bi OLUWA ti wi, ati gẹgẹ bi OLUWA ti bura fun wọn: oju si pọ́n wọn pupọ̀pupọ̀.

16. OLUWA si gbé awọn onidajọ dide, ti o gbà wọn li ọwọ́ awọn ẹniti nkó wọn lẹrù.

A. Oni 2