A. Oni 19:11-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀.

12. Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, Awa ki o yà si ilu ajeji kan, ti ki iṣe ti awọn ọmọ Israeli; awa o rekọja si Gibea.

13. On si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Wá jẹ ki a sunmọ ọkan ninu ibi wọnyi; ki a si wọ̀ si Gibea, tabi Rama.

14. Nwọn si rekọja, nwọn lọ: õrùn si wọ̀ bá wọn leti Gibea, ti iṣe ti Benjamini.

15. Nwọn si yà si Gibea lati wọ̀ ọ, ati lati sùn nibẹ̀: o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, o joko ni igboro ilu na: nitoriti kò sí ẹnikan ti o gbà wọn sinu ile rẹ̀ lati wọ̀.

16. Si kiyesi, i ọkunrin arugbo kan si nti ibi iṣẹ rẹ̀ bọ̀ lati inu oko wá li alẹ; ọkunrin na jẹ́ ara ilẹ òke Efraimu pẹlu, on si ṣe atipo ni Gibea: ṣugbọn ẹ̀ya Benjamini ni awọn ọkunrin ibẹ̀ iṣe.

17. Nigbati o gbé oju rẹ̀ soke, o si ri èro kan ni igboro ilu; ọkunrin arugbo na si wipe, Nibo ni iwọ nrè? nibo ni iwọ si ti wá?

18. On si wi fun u pe, Awa nrekọja lati Beti-lehemu-juda lọ si ìha ọhùn ilẹ òke Efraimu; lati ibẹ̀ li emi ti wá, emi si ti lọ si Beti-lehemu-juda: nisisiyi emi nlọ si ile OLUWA; kò si sí ẹnikan ti o gbà mi si ile.

19. Bẹ̃ni koriko ati ohunjijẹ mbẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ wa; onjẹ ati ọti-waini si mbẹ fun mi pẹlu, ati fun iranṣẹbinrin rẹ, ati fun ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ awọn iranṣẹ rẹ: kò si sí ainí ohunkohun.

20. Ọkunrin arugbo na si wipe, Alafia fun ọ; bi o ti wù ki o ri, jẹ ki gbogbo ainí rẹ ki o pọ̀ si apa ọdọ mi; ọkanṣoṣo ni, máṣe sùn si igboro.

21. Bẹ̃li o mú u wá sinu ile rẹ̀, o si fi onjẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ: nwọn wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, nwọn jẹ nwọn si mu.

A. Oni 19