A. Oni 19:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọjọ́ wọnni, nigbati kò sí ọba kan ni Israeli, ọkunrin Lefi kan nṣe atipo ni ìha ọhún ilẹ òke Efraimu, ẹniti o si mú àle kan lati Beti-lehemu-juda wá.

2. Àle rẹ̀ na si ṣe panṣaga si i, o si lọ kuro lọdọ rẹ̀ si ile baba rẹ̀ si Beti-lehemu-juda, o si wà ni ibẹ̀ ni ìwọn oṣù mẹrin.

3. Ọkọ rẹ̀ si dide, o si tọ̀ ọ lọ, lati tù u ninu, ati lati mú u pada, ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mbẹ pẹlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ meji: ọmọbinrin na si mú u wá sinu ile baba rẹ̀: nigbati baba rẹ̀ si ri i, o yọ̀ lati pade rẹ̀.

4. Ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si da a duro; o si bá a joko ni ijọ́ mẹta; nwọn jẹ nwọn mu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.

5. O si ṣe ni ijọ́ kẹrin, nwọn jí ni kùtukutu, o si dide lati lọ: baba ọmọbinrin na si wi fun ana rẹ̀ pe, Fi òkele onjẹ kan tẹlẹ inu, lẹhin na ki ẹ ma lọ.

6. Nwọn si joko, awọn mejeji si jùmọ jẹ, nwọn si mu: baba ọmọbinrin na si wi fun ọkunrin na pe, Mo bẹ̀ ọ, farabalẹ, ki o si duro li oru oni, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn.

A. Oni 19