1. O si ṣe li ọjọ́ wọnni, nigbati kò sí ọba kan ni Israeli, ọkunrin Lefi kan nṣe atipo ni ìha ọhún ilẹ òke Efraimu, ẹniti o si mú àle kan lati Beti-lehemu-juda wá.
2. Àle rẹ̀ na si ṣe panṣaga si i, o si lọ kuro lọdọ rẹ̀ si ile baba rẹ̀ si Beti-lehemu-juda, o si wà ni ibẹ̀ ni ìwọn oṣù mẹrin.
3. Ọkọ rẹ̀ si dide, o si tọ̀ ọ lọ, lati tù u ninu, ati lati mú u pada, ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mbẹ pẹlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ meji: ọmọbinrin na si mú u wá sinu ile baba rẹ̀: nigbati baba rẹ̀ si ri i, o yọ̀ lati pade rẹ̀.
4. Ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si da a duro; o si bá a joko ni ijọ́ mẹta; nwọn jẹ nwọn mu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
5. O si ṣe ni ijọ́ kẹrin, nwọn jí ni kùtukutu, o si dide lati lọ: baba ọmọbinrin na si wi fun ana rẹ̀ pe, Fi òkele onjẹ kan tẹlẹ inu, lẹhin na ki ẹ ma lọ.
6. Nwọn si joko, awọn mejeji si jùmọ jẹ, nwọn si mu: baba ọmọbinrin na si wi fun ọkunrin na pe, Mo bẹ̀ ọ, farabalẹ, ki o si duro li oru oni, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn.
7. Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, ana rẹ̀ si rọ̀ ọ, o si tun sùn sibẹ̀.
8. On si dide ni kùtukutu ọjọ́ karun lati lọ, baba ọmọbinrin na si wipe, Mo bẹ̀ ọ, tù ara rẹ lara, ki ẹ si duro titi di irọlẹ; awọn mejeji si jẹun.
9. Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, on, ati àle rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀, ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ọjọ́ di aṣalẹ tán, emi bẹ̀ ọ duro li oru yi: kiyesi i ọjọ́ lọ tán, sùn sihin, ki inu rẹ ki o le dùn: ni kùtukutu ọla ẹ tète bọ́ si ọ̀na nyin, ki iwọ ki o le lọ ile.
10. Ọkunrin na si kọ̀ lati sùn, o si dide o si lọ, o si dé ọkankan Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): kẹtẹkẹtẹ meji ti a dì ni gãri wà lọdọ rẹ̀, àle rẹ̀ pẹlu si wà lọdọ rẹ̀.
11. Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀.
12. Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, Awa ki o yà si ilu ajeji kan, ti ki iṣe ti awọn ọmọ Israeli; awa o rekọja si Gibea.
13. On si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Wá jẹ ki a sunmọ ọkan ninu ibi wọnyi; ki a si wọ̀ si Gibea, tabi Rama.
14. Nwọn si rekọja, nwọn lọ: õrùn si wọ̀ bá wọn leti Gibea, ti iṣe ti Benjamini.