A. Oni 18:16-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun ninu awọn ọmọ Dani, duro li ẹnu-ọ̀na.

17. Awọn ọkunrin marun ti o ti lọ iṣe amí ilẹ na gòke lọ, nwọn si wá si ibẹ̀ na, nwọn si kó ere fifin, ati efodu, ati terafimu, ati ere didà na: alufa na si duro li ẹnu-ọ̀na pẹlu awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun.

18. Nigbati awọn wọnyi si wọ̀ ile Mika lọ, nwọn si mú ere fifin, efodu, ati terafimu, ati ere didà na, nigbana li alufa na wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe yi?

19. Nwọn si wi fun u pe, Dakẹ, fi ọwọ́ rẹ lé ẹnu rẹ, ki o si ma bá wa lọ, ki o si ma ṣe baba fun wa ati alufa: o ha san fun ọ lati ṣe alufa fun ile ọkunrin kan, tabi ki iwọ ki o ṣe alufa fun ẹ̀ya ati idile kan ni Israeli?

20. Inu alufa na si dùn, o si mú efodu, ati terafimu, ati ere fifin, o si bọ̀ sãrin awọn enia na.

21. Bẹ̃ni nwọn yipada nwọn si lọ, nwọn tì awọn ọmọ kekere ati ẹran ati ẹrù siwaju wọn.

22. Nigbati nwọn si lọ jìna si ile Mika, awọn ọkunrin ti o wà ninu ile wọnni ti o sunmọ ile Mika kó ara wọn jọ, nwọn si lé awọn ọmọ Dani bá.

23. Nwọn si kọ si awọn ọmọ Dani. Nwọn si yi oju wọn pada, nwọn wi fun Mika pe, Kili o ṣe ọ, ti iwọ fi kó irú ẹgbẹ bẹ̃ lẹhin wá?

24. On si wipe, Ẹnyin kó awọn oriṣa mi ti mo ṣe lọ, ẹ si mú alufa, ẹ si lọ, kini mo si tun ní? kili eyiti ẹnyin wi fun mi pe, Kili o ṣe ọ?

25. Awọn ọmọ Dani si wi fun u pe, Máṣe jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ lãrin wa, ki awọn oninuṣùṣu ki o má bã kọlù nyin, iwọ a si sọ ẹmi rẹ nù, ati ẹmi awọn ara ile rẹ.

26. Awọn ọmọ Dani si ba ọ̀na wọn lọ: nigbati Mika si ri i pe, nwọn lagbara jù on lọ, on si yipada, o si pada lọ sinu ile rẹ̀.

27. Nwọn si kó awọn nkan wọnni ti Mika ṣe, ati alufa ti o ní, nwọn si wá si Laiṣi sọdọ awọn enia ti o wà ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru, nwọn si fi oju idà kọlù wọn, nwọn si fi iná kun ilu na.

28. Kò si sí olugbala, nitoriti o jìna si Sidoni, nwọn kò si bá ẹnikẹni ṣe; o si wà ni afonifoji ti o wà ni Beti-rehobu. Nwọn si kọ́ ilu na, nwọn si ngbé inu rẹ̀.

29. Nwọn si pè orukọ ilu na ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn, ẹniti a bi fun Israeli: ṣugbọn Laiṣi li orukọ ilu na li atijọ rí.

30. Awọn ọmọ Dani si gbé ere fifin na kalẹ: ati Jonatani, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, on ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin li o nṣe alufa fun ẹ̀ya Dani titi o fi di ọjọ́ ti a fi kó ilẹ na ni igbekun lọ.

31. Nwọn si gbé ere fifin ti Mika ṣe kalẹ ni gbogbo ọjọ́ ti ile Ọlọrun fi wà ni Ṣilo.

A. Oni 18