A. Oni 18:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nwọn si yà sibẹ̀, nwọn si wá si ile ọmọkunrin Lefi na, ani si ile Mika, nwọn si bère alafia rẹ̀.

16. Awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun ninu awọn ọmọ Dani, duro li ẹnu-ọ̀na.

17. Awọn ọkunrin marun ti o ti lọ iṣe amí ilẹ na gòke lọ, nwọn si wá si ibẹ̀ na, nwọn si kó ere fifin, ati efodu, ati terafimu, ati ere didà na: alufa na si duro li ẹnu-ọ̀na pẹlu awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun.

18. Nigbati awọn wọnyi si wọ̀ ile Mika lọ, nwọn si mú ere fifin, efodu, ati terafimu, ati ere didà na, nigbana li alufa na wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe yi?

19. Nwọn si wi fun u pe, Dakẹ, fi ọwọ́ rẹ lé ẹnu rẹ, ki o si ma bá wa lọ, ki o si ma ṣe baba fun wa ati alufa: o ha san fun ọ lati ṣe alufa fun ile ọkunrin kan, tabi ki iwọ ki o ṣe alufa fun ẹ̀ya ati idile kan ni Israeli?

20. Inu alufa na si dùn, o si mú efodu, ati terafimu, ati ere fifin, o si bọ̀ sãrin awọn enia na.

21. Bẹ̃ni nwọn yipada nwọn si lọ, nwọn tì awọn ọmọ kekere ati ẹran ati ẹrù siwaju wọn.

22. Nigbati nwọn si lọ jìna si ile Mika, awọn ọkunrin ti o wà ninu ile wọnni ti o sunmọ ile Mika kó ara wọn jọ, nwọn si lé awọn ọmọ Dani bá.

23. Nwọn si kọ si awọn ọmọ Dani. Nwọn si yi oju wọn pada, nwọn wi fun Mika pe, Kili o ṣe ọ, ti iwọ fi kó irú ẹgbẹ bẹ̃ lẹhin wá?

A. Oni 18