A. Oni 18:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: ati li ọjọ́ wọnni ẹ̀ya Dani nwá ilẹ-iní kan lati joko si; nitoripe titi o fi di ọjọ́ na, ilẹ-iní wọn lãrin awọn ẹ̀ya Israeli kò ti ibọ́ si ọwọ́ wọn.

2. Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.

3. Nigbati nwọn wà leti ile Mika, nwọn si mọ̀ ohùn ọmọkunrin Lefi na: nwọn si wọ̀ inu ile na, nwọn si wi fun u pe, Tali o mú ọ wá ihinyi? kini iwọ si nṣe ni ihinyi? kini iwọ si ní nihin?

4. On si wi fun wọn pe, Bayibayi ni Mika ṣe fun mi, o gbà mi si iṣẹ, alufa rẹ̀ li emi si iṣe.

5. Nwọn si wi fun u pe, Bère lọdọ Ọlọrun, awa bẹ̀ ọ, ki awa ki o le mọ̀ bi ọ̀na wa ti awa nlọ yio jasi rere.

6. Alufa na si wi fun wọn pe, Ẹ ma lọ li alafia: ọ̀na nyin ti ẹnyin nlọ mbẹ niwaju OLUWA.

7. Nigbana li awọn ọkunrin mararun na lọ, nwọn si dé Laiṣi, nwọn si ri awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, bi nwọn ti joko laibẹ̀ru, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Sidoni, ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru; kò si sí olori kan ni ilẹ na, ti iba mu oju tì wọn li ohunkohun, nwọn si jìna si awọn ara Sidoni, nwọn kò si ba ẹnikẹni ṣe.

8. Nwọn si wá sọdọ awọn arakunrin wọn si Sora ati Eṣtaolu: awọn arakunrin wọn si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin wi?

A. Oni 18