1. LI ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: ati li ọjọ́ wọnni ẹ̀ya Dani nwá ilẹ-iní kan lati joko si; nitoripe titi o fi di ọjọ́ na, ilẹ-iní wọn lãrin awọn ẹ̀ya Israeli kò ti ibọ́ si ọwọ́ wọn.
2. Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
3. Nigbati nwọn wà leti ile Mika, nwọn si mọ̀ ohùn ọmọkunrin Lefi na: nwọn si wọ̀ inu ile na, nwọn si wi fun u pe, Tali o mú ọ wá ihinyi? kini iwọ si nṣe ni ihinyi? kini iwọ si ní nihin?
4. On si wi fun wọn pe, Bayibayi ni Mika ṣe fun mi, o gbà mi si iṣẹ, alufa rẹ̀ li emi si iṣe.
5. Nwọn si wi fun u pe, Bère lọdọ Ọlọrun, awa bẹ̀ ọ, ki awa ki o le mọ̀ bi ọ̀na wa ti awa nlọ yio jasi rere.
6. Alufa na si wi fun wọn pe, Ẹ ma lọ li alafia: ọ̀na nyin ti ẹnyin nlọ mbẹ niwaju OLUWA.