11. O si rọ̀ ọmọ Lefi na lọrùn lati bá ọkunrin na joko; ọmọkunrin na si wà lọdọ rẹ̀ bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀.
12. Mika si yà ọmọ Lefi na sọ̀tọ, ọmọkunrin na si wa di alufa rẹ̀, o si wà ninu ile Mika.
13. Mika si wipe, Njẹ nisisiyi li emi tó mọ̀ pe, OLUWA yio ṣe mi li ore, nitoriti emi li ọmọ Lefi kan li alufa mi.