16. O si ṣe, nigbati o fi ọ̀rọ rẹ̀ rọ̀ ọ li ojojumọ́, ti o si ṣe e laisimi, tobẹ̃ ti sũru fi tan ọkàn rẹ̀ dé ikú.
17. Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
18. Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn.
19. O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.
20. On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on.
21. Awọn Filistini sì mú u, nwọn si yọ ọ li oju mejeji; nwọn si mú u sọkalẹ wá si Gasa, nwọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ̀ idẹ dè e: on si nlọ-ọlọ ni ile-tubu.
22. Ṣugbọn irun ori rẹ̀ bẹ̀rẹsi hù lẹhin igbati a ti fá a tán.
23. Nigbana ni awọn ijoye Filistini kó ara wọn jọ lati ru ẹbọ nla kan si Dagoni oriṣa wọn, ati lati yọ̀: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi Samsoni ọtá wa lé wa lọwọ.
24. Nigbati awọn enia si ri i, nwọn fi iyin fun oriṣa wọn: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi ọtá wa lé wa lọwọ, ẹniti npa ilẹ wa run, ti o si pa ọ̀pọlọpọ enia ninu wa.
25. O si ṣe, nigbati inu wọn dùn, ni nwọn wipe, Ẹ pè Samsoni, ki o wa ṣiré fun wa. Nwọn si pè Samsoni lati inu ile-itubu wá; o si ṣiré niwaju wọn: nwọn si mu u duro lãrin ọwọ̀n meji.
26. Samsoni si wi fun ọmọkunrin ti o di ọwọ́ rẹ̀ mú pe, Jẹ ki emi ki o fọwọbà awọn ọwọ̀n ti ile joko lé, ki emi ki o le faratì wọn.
27. Njẹ ile na kún fun ọkunrin ati obinrin; gbogbo awọn ijoye Filistini si wà nibẹ̀; awọn ti o si wà lori orule, ati ọkunrin ati obinrin, o to ìwọn ẹgbẹdogun enia, ti nworan Samsoni nigbati o nṣiré.
28. Samsoni si kepè OLUWA, o si wipe, Oluwa ỌLỌRUN, emi bẹ̀ ọ, ranti mi, ki o si jọ̃ fun mi li agbara lẹ̃kanṣoṣo yi, Ọlọrun, ki emi ki o le gbẹsan lẹ̃kan lara awọn Filistini nitori oju mi mejeji.
29. Samsoni si dì ọwọ̀n ãrin mejeji na mú lori eyiti ile na joko, o si faratì wọn, o fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú kan, o si fi ọwọ́ òsi rẹ̀ mú ekeji.
30. Samsoni si wipe, Jẹ ki nkú pẹlu awọn Filistini. O si fi gbogbo agbara rẹ̀ bẹ̀rẹ; ile na si wó lù awọn ijoye wọnni, ati gbogbo enia ti o wà ninu rẹ̀. Bẹ̃li awọn okú ti o pa ni ikú rẹ̀, pọjù awọn ti o pa li ãyè rẹ̀ lọ.
31. Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo idile baba rẹ̀ sọkalẹ wá, nwọn si gbé e gòke, nwọn si sin i lãrin Sora on Eṣtaolu ni ibojì Manoa baba rẹ̀. O si ṣe idajọ Israeli li ogún ọdún.