1. SAMSONI si lọ si Gasa, o si ri obinrin panṣaga kan nibẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ.
2. Awọn ara Gasa si gbọ́ pe, Samsoni wá si ihin. Nwọn si yi i ká, nwọn lùmọ́ ni gbogbo oru na li ẹnu-bode ilu na, nwọn si dakẹ jẹ ni gbogbo oru na, wipe, Li owurọ̀ nigbati ilẹ ba mọ́, li awa a pa a.
3. Samsoni si dubulẹ titi o fi di ãrin ọganjọ, o si dide lãrin ọganjọ, o si gbé ilẹkun-ibode ilu na, ati opó mejeji, o si fà wọn tu pẹlu idabu-ilẹ̀kùn, o gbé wọn lé ejika rẹ̀, o si rù wọn lọ si ori òke kan ti o wà niwaju Hebroni.
4. O si ṣe lẹhin eyinì, o si fẹ́ obinrin kan li afonifoji Soreki, a si ma pè orukọ rẹ̀ ni Delila.
5. Awọn ijoye Filistini tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Tàn a, ki o si mọ̀ ibiti agbara nla rẹ̀ gbé wà, ati bi awa o ti ṣe le bori rẹ̀, ki awa ki o le dè e lati jẹ ẹ niyà: olukuluku wa yio si fun ọ ni ẹdẹgbẹfa owo fadakà.
6. Delila si wi fun Samsoni pe, Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi, nibo li agbara nla rẹ gbé wà, ati kili a le fi dè ọ lati jẹ ọ niyà.
7. Samsoni si wi fun u pe, Bi a ba fi okùn tutù meje ti a kò ságbẹ dè mi, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
8. Nigbana li awọn ijoye Filistini mú okùn tutù meje tọ̀ ọ wá ti a kò ságbẹ, o si fi okùn wọnni dè e.