5. Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu.
6. Nigbana li awọn Filistini wipe, Tani ṣe eyi? Nwọn si dahùn pe, Samsoni, ana ara Timna ni, nitoriti o gbà obinrin rẹ̀, o si fi i fun ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Filistini si gòke wá, nwọn si fi iná sun obinrin na ati baba rẹ̀.
7. Samsoni si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin ba ṣe irú eyi, dajudaju emi o gbẹsan lara nyin, lẹhin na emi o si dẹkun.