12. Nwọn si wi fun u pe, Awa sọkalẹ wá lati dè ọ, ki awa ki o le fi ọ lé awọn Filistini lọwọ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ bura fun mi, pe ẹnyin tikara nyin ki yio pa mi.
13. Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.
14. Nigbati o dé Lehi, awọn Filistini hó bò o: ẹmi OLUWA si bà lé e, okùn ti o si wà li apa rẹ̀ si wa dabi okùn-ọ̀gbọ ti o ti jóna, ìde rẹ̀ si tú kuro li ọwọ́ rẹ̀.
15. O si ri pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ titun kan, o si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si fi i pa ẹgbẹrun ọkunrin.
16. Samsoni si wipe, Pari-ẹrẹkẹ kan ni mo fi pa òkiti kan, òkiti meji; pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ kan ni mo fi pa ẹgbẹrun ọkunrin.
17. O si ṣe, nigbati o pari ọ̀rọ isọ tán, o sọ pari-ẹrẹkẹ na nù, o si pè ibẹ̀ na ni Ramati-lehi.
18. Ongbẹ si ngbẹ ẹ gidigidi, o si kepè OLUWA, wipe, Iwọ ti fi ìgbala nla yi lé ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ: nisisiyi emi o kú nitori ongbẹ, emi o si bọ́ si ọwọ́ awọn alaikọlà.
19. Ṣugbọn Ọlọrun si là ibi kòto kan ti o wà ni Lehi, nibẹ̀ li omi si sun jade; nigbati on si mu u tán ẹmi rẹ̀ si tun pada, o si sọjí: nitorina ni a ṣe pè orukọ ibẹ̀ na ni Eni-hakkore, ti o wà ni Lehi, titi o fi di oni-oloni.
20. On si ṣe idajọ Israeli li ọjọ́ awọn Filistini li ogún ọdún.