10. Obinrin na si yara kánkán, o si sure, o si sọ fun ọkọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Kiyesi i, ọkunrin ti o tọ̀ mi wá ni ijelo farahàn mi.
11. Manoa si dide, o si tẹle aya rẹ̀, o si wá sọdọ ọkunrin na, o si bi i pe, Iwọ li ọkunrin na ti o bá obinrin na sọ̀rọ? On si wipe, Emi ni.
12. Manoa si wipe, Njẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ: ìwa ọmọ na yio ti jẹ́, iṣẹ rẹ̀ yio ti jẹ́?
13. Angeli OLUWA si wi fun Manoa pe, Ni gbogbo eyiti mo sọ fun obinrin na ni ki o kiyesi.
14. Ki o má ṣe jẹ ohun kan ti o ti inu àjara wá, ki o má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ ohun aimọ́ kan; gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun u ni ki o kiyesi.
15. Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o da ọ duro, titi awa o si fi pèse ọmọ ewurẹ kan fun ọ.
16. Angeli OLUWA na si wi fun Manoa pe, Bi iwọ tilẹ da mi duro, emi ki yio jẹ ninu àkara rẹ: bi iwọ o ba si ru ẹbọ sisun kan, OLUWA ni ki iwọ ki o ru u si. Nitori Manoa kò mọ̀ pe angeli OLUWA ni iṣe.
17. Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Orukọ rẹ, nitori nigbati ọ̀rọ rẹ ba ṣẹ ki awa ki o le bọlá fun ọ?
18. Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi, kiyesi i, Iyanu ni.
19. Manoa si mú ọmọ ewurẹ kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ, o si ru u lori apata kan si OLUWA: angeli na si ṣe ohun iyanu, Manoa ati obinrin rẹ̀ si nwò o.
20. O si ṣe ti ọwọ́-iná na nlọ soke ọrun lati ibi-pẹpẹ na wá, angeli OLUWA na si gòke ninu ọwọ́-iná ti o ti ibi-pẹpẹ jade wá. Manoa ati aya rẹ̀ si nwò o; nwọn si dojubolẹ.
21. Ṣugbọn angeli OLUWA na kò si tun farahàn fun Manoa tabi aya rẹ̀ mọ́. Nigbana ni Manoa to wa mọ̀ pe, angeli OLUWA ni iṣe.
22. Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun.
23. Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi.