A. Oni 12:13-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Lẹhin rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hilleli, ti Piratoni, ṣe idajọ Israeli.

14. On si lí ogoji ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ ti ngùn ãdọrin ọmọ kẹtẹkẹtẹ: on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹjọ.

15. Abdoni ọmọ Hilleli ti Piratoni si kú, a si sin i ni Piratoni ni ilẹ Efraimu, li òke awọn Amaleki.

A. Oni 12