3. Nigbana ni Jefta sá kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, on si joko ni ile Tobu: awọn enia lasan si kó ara wọn jọ sọdọ Jefta, nwọn si bá a jade lọ,
4. O si ṣe lẹhin ijọ́ melokan, awọn ọmọ Ammoni bá Israeli jagun.
5. O si ṣe nigbati awọn Ammoni bá Israeli jagun, awọn àgba Gileadi si lọ mú Jefta lati ilẹ Tobu wa.
6. Nwọn si wi fun Jefta pe, Wá, jẹ́ olori wa, ki awa ki o le bá awọn ọmọ Ammoni jà.
7. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Ẹnyin kò ha ti korira mi, ẹnyin kò ha ti lé mi kuro ni ile baba mi? ẽ si ti ṣe ti ẹnyin fi tọ̀ mi wá nisisiyi nigbati ẹnyin wà ninu ipọnju?
8. Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Nitorina li awa ṣe pada tọ̀ ọ nisisiyi, ki iwọ ki o le bá wa lọ, ki o si bá awọn ọmọ Ammoni jà, ki o si jẹ́ olori wa ati ti gbogbo awọn ara Gileadi.
9. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Bi ẹnyin ba mú mi pada lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti OLUWA ba si fi wọn fun mi, emi o ha jẹ́ olori nyin bi?