23. Njẹ bẹ̃ni OLUWA, Ọlọrun Israeli, lé awọn Amori kuro niwaju Israeli awọn enia rẹ̀, iwọ o ha gbà a bi?
24. Iwọ ki yio ha gbà eyiti Kemoṣu oriṣa rẹ fi fun ọ lati ní? Bẹ̃li ẹnikẹni ti OLUWA Ọlọrun wa ba lé kuro niwaju wa, ilẹ wọn ni awa o gbà.
25. Njẹ iwọ ha san jù Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu? on ha bá Israeli ṣe gbolohùn asọ̀ rí, tabi o ha bá wọn jà rí?
26. Nigbati Israeli fi joko ni Heṣboni ati awọn ilu rẹ̀, ati ni Aroeri ati awọn ilu rẹ̀, ati ni gbogbo awọn ilu ti o wà lọ titi de ẹba Arnoni, li ọdunrun ọdún; ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a li akokò na?
27. Nitorina emi kò ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ li o ṣẹ̀ mi ni bibá mi jà: ki OLUWA, Onidajọ, ki o ṣe idajọ li oni lãrin awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Ammoni.
28. Ṣugbọn ọba awọn ọmọ Ammoni kò fetisi ọ̀rọ Jefta, ti o rán si i.
29. Nigbana li ẹmi OLUWA bà lé Jefta, on si kọja Gileadi ati Manasse, o si kọja Mispa ti Gileadi, ati lati Mispa ti Gileadi o si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.
30. Jefta si jẹ́ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, o si wi pe, Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ,
31. Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun.
32. Jefta si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni, lati bá wọn jà; OLUWA si fi nwọn lé e lọwọ.
33. On si pa wọn ni ipakupa lati Aroeri lọ, titi dé atiwọ̀ Miniti, ani ogún ilu, titi o fi dé Abeli-kiramimu. Bẹ̃li a ṣẹgun awọn ọmọ Ammoni niwaju awọn ọmọ Israeli.