A. Oni 11:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nigbana ni Israeli rán onṣẹ si ọba Edomu, wipe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja ni ilẹ rẹ: ṣugbọn ọba Edomu kò gbọ́. Bẹ̃ gẹgẹ o si ranṣẹ si ọba Moabu pẹlu: ṣugbọn kò fẹ́: Israeli si joko ni Kadeṣi.

18. Nigbana ni o rìn lãrin aginjù o si yi ilẹ Edomu, ati ilẹ Moabu ká, o si yọ ni ìha ìla-õrùn ilẹ Moabu, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ṣugbọn nwọn kò wá sinu àla Moabu, nitoripe Arnoni ni àla Moabu.

19. Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn Amori, ọba Heṣboni; Israeli si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o kọja lãrin ilẹ rẹ si ipò mi.

20. Ṣugbọn Sihoni kò gbẹkẹle Israeli lati kọja li àgbegbe rẹ̀: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo enia rẹ̀ jọ, nwọn si dó ni Jahasi, nwọn si bá Israeli jagun.

21. OLUWA, Ọlọrun Israeli, si fi Sihoni, ati gbogbo enia rẹ̀ lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn: Israeli si gbà gbogbo ilẹ awọn Amori, awọn enia ilẹ na.

22. Nwọn si gbà gbogbo àgbegbe awọn Amori, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati lati aginjù titi dé Jordani.

23. Njẹ bẹ̃ni OLUWA, Ọlọrun Israeli, lé awọn Amori kuro niwaju Israeli awọn enia rẹ̀, iwọ o ha gbà a bi?

A. Oni 11