A. Oni 11:12-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Jefta si rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni, wipe, Kili o ṣe temi tirẹ, ti iwọ fi tọ̀ mi wá, lati jà ni ilẹ mi?

13. Ọba awọn ọmọ Ammoni si da awọn onṣẹ Jefta lohùn pe, Nitoriti Israeli ti gbà ilẹ mi, nigbati nwọn gòke ti Egipti wá, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati titi dé Jordani: njẹ́ nisisiyi fi ilẹ wọnni silẹ li alafia.

14. Jefta si tun rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni:

15. O si wi fun u pe, Bayi ni Jefta wi, Israeli kò gbà ilẹ Moabu, tabi ilẹ awọn ọmọ Ammoni:

A. Oni 11