1. JEFTA ara Gileadi si jẹ́ akọni ọkunrin, on si jẹ́ ọmọ panṣaga obinrin kan: Gileadi si bi Jefta.
2. Aya Gileadi si bi awọn ọmọkunrin fun u; nigbati awọn ọmọ aya na si dàgba, nwọn si lé Jefta jade, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ki yio jogún ni ile baba wa; nitoripe ọmọ ajeji obinrin ni iwọ iṣe.
3. Nigbana ni Jefta sá kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, on si joko ni ile Tobu: awọn enia lasan si kó ara wọn jọ sọdọ Jefta, nwọn si bá a jade lọ,
4. O si ṣe lẹhin ijọ́ melokan, awọn ọmọ Ammoni bá Israeli jagun.
5. O si ṣe nigbati awọn Ammoni bá Israeli jagun, awọn àgba Gileadi si lọ mú Jefta lati ilẹ Tobu wa.
6. Nwọn si wi fun Jefta pe, Wá, jẹ́ olori wa, ki awa ki o le bá awọn ọmọ Ammoni jà.
7. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Ẹnyin kò ha ti korira mi, ẹnyin kò ha ti lé mi kuro ni ile baba mi? ẽ si ti ṣe ti ẹnyin fi tọ̀ mi wá nisisiyi nigbati ẹnyin wà ninu ipọnju?