A. Oni 10:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN Abimeleki li ẹnikan si dide lati gbà Israeli là, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, ọkunrin Issakari kan; o si ngbé Ṣamiri li òke Efraimu.

2. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹtalelogun o si kú, a si sin i ni Ṣamiri.

3. Lẹhin rẹ̀ ni Jairi dide, ara Gileadi; o si ṣe idajọ Israeli li ọdún mejilelogun.

4. On si ní ọgbọ̀n ọmọkunrin ti ngùn ọgbọ̀n ọmọ kẹtẹkẹtẹ, nwọn si ní ọgbọ̀n ilu ti a npè ni Haffoti-jairi titi o fi di oni, eyiti o wà ni ilẹ Gileadi.

5. Jairi si kú, a si sin i ni Kamoni.

6. Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu, ati Aṣtarotu, ati awọn oriṣa Siria, ati awọn oriṣa Sidoni, ati awọn oriṣa Moabu, ati awọn oriṣa awọn ọmọ Ammoni, ati awọn oriṣa awọn Filistini; nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn kò si sìn i.

7. Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni.

8. Li ọdún na nwọn ni awọn ọmọ Israeli lara, nwọn si pọ́n wọn loju: ọdún mejidilogun ni nwọn fi ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ti o wà ni ìha keji Jordani ni ilẹ awọn Amori, ti o wà ni Gileadi, lara.

A. Oni 10