34. Awọn Amori si fi agbara tì awọn ọmọ Dani sori òke: nitoripe nwọn kò jẹ ki nwọn ki o sọkalẹ wá si afonifoji.
35. Awọn Amori si ngbé òke Heresi, ni Aijaloni, ati ni Ṣaalbimu: ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹniti nsìn.
36. Àla awọn Amori si ni lati ìgoke lọ si Akrabbimu, lati ibi apata lọ si òke.