7. Nítorí alabojuto ìjọ níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọrun. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí yóo máa ṣe ti inú ara rẹ̀, tabi kí ó jẹ́ onínúfùfù. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà, tabi ẹni tí ó ní ìwọ̀ra nípa ọ̀rọ̀ owó.
8. Ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ati máa ṣe àlejò, tí ó sì fẹ́ ohun rere, ó yẹ kí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, olódodo, olùfọkànsìn, ẹni tí ó ń kó ara rẹ̀ níjàánu.
9. Kí ó di ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí a ti fi kọ́ ọ mú ṣinṣin, kí ó baà lè ní ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ẹ̀kọ́ tí ó yè, kí ó sì lè bá àwọn alátakò wí.
10. Nítorí àwọn alágídí pọ̀, tí wọn ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn ẹlẹ́tàn, pàápàá jùlọ lára àwọn ọ̀kọlà.
11. Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ.
14. Kí wọn má máa lo àkókò wọn lórí ìtàn àròsọ àwọn Juu ati ìlànà àwọn eniyan tí wọ́n ti yapa kúrò lọ́nà òtítọ́.