1. Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí.Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn,
10. Nítorí àwọn alágídí pọ̀, tí wọn ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn ẹlẹ́tàn, pàápàá jùlọ lára àwọn ọ̀kọlà.
11. Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ.
12-13. Ẹnìkan ninu wọn tí ó jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn wolii wọn sọ pé, “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kirete, ẹhànnà, ẹranko, ọ̀lẹ, alájẹkì.” Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà má gbojú fún wọn, bá wọn wí kí wọ́n lè ní igbagbọ tí ó pé.