Sefanaya 3:4-6 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Oníwọ̀ra ati alaiṣootọ eniyan ni àwọn wolii rẹ̀, àwọn alufaa rẹ̀ sì ti sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́, wọ́n yí òfin Ọlọrun po fún anfaani ara wọn.

5. Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ.

6. OLUWA wí pé: “Mo ti pa àwọn orílẹ̀-èdè run; ilé-ìṣọ́ wọn sì ti di àlàpà; mo ti ba àwọn ìgboro wọn jẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè rìn níbẹ̀; àwọn ìlú wọn ti di ahoro, láìsí olùgbé kankan níbẹ̀.

Sefanaya 3