1. Ìwọ ìlú ọlọ̀tẹ̀, o gbé! Ìlú oníbàjẹ́ ati aninilára.
2. Ìlú tí kò gba ìmọ̀ràn ati ìbáwí, tí kò gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí kò sì súnmọ́ Ọlọrun rẹ̀.
3. Àwọn olóyè rẹ̀ ní ìwọ̀ra bíi kinniun tí ń bú ramúramù; àwọn onídàájọ́ rẹ̀ dàbí ìkookò tí ń jẹ ní aṣálẹ̀ tí kì í jẹ ẹran tí ó bá pa lájẹṣẹ́kù di ọjọ́ keji.
4. Oníwọ̀ra ati alaiṣootọ eniyan ni àwọn wolii rẹ̀, àwọn alufaa rẹ̀ sì ti sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́, wọ́n yí òfin Ọlọrun po fún anfaani ara wọn.
5. Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ.