1. Àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu wá, wọ́n gbé àpótí OLUWA náà lọ sí ilé Abinadabu, tí ń gbé orí òkè kan. Wọ́n ya Eleasari, ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, láti máa bojútó àpótí OLUWA náà.
2. Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.