Samuẹli Kinni 23:3-5 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àwọn ọkunrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì sọ fún un pé, “Ní Juda tí a wà níhìn-ín, inú ewu ni a wà, báwo ni yóo ti rí nígbà tí a bá tún lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila?”

4. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ OLUWA lẹ́ẹ̀kan sí i pé, bóyá kí òun lọ tabi kí òun má lọ. OLUWA sì dáhùn pé, “Lọ sí Keila nítorí n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Filistia.”

5. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila, wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wọn, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe gba àwọn ará Keila sílẹ̀.

Samuẹli Kinni 23