22. Dafidi fún olùtọ́jú ẹrù àwọn ọmọ ogun ní oúnjẹ tí ó gbé lọ, ó sì sáré tọ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sójú ogun láti kí wọn.
23. Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Goliati wá láti pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà. Ó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń sọ ọ́; Dafidi sì gbọ́.
24. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli rí Goliati, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n sì sá lọ.
25. Wọ́n ní, “Ẹ wo ọkunrin yìí, ẹ gbọ́ bí ó ti ń pe Israẹli níjà? Ọba sì ti sọ pé ẹni tí ó bá lè pa á yóo gba ẹ̀bùn lọpọlọpọ. Òun yóo sì fi ọmọbinrin òun fún olúwarẹ̀, ilé baba rẹ̀ yóo sì di òmìnira ní ilẹ̀ Israẹli: kò ní san owó orí mọ́.”