31. Wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini ní ọjọ́ náà, láti Mikimaṣi títí dé Aijaloni; ó sì rẹ àwọn eniyan náà gidigidi.
32. Nítorí náà, wọ́n sáré sí ìkógun, wọ́n pa àwọn aguntan ati mààlúù ati ọmọ mààlúù, wọ́n sì ń jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.
33. Wọ́n bá lọ sọ fún Saulu pé, “Àwọn eniyan ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”Saulu bá wí pé, “Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni ẹ hù yìí. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.”
34. Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.
35. Saulu bá tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA. Pẹpẹ yìí ni pẹpẹ kinni tí Saulu tẹ́ fún OLUWA.