Samuẹli Keji 4:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.

6. Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé.

7. Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn.

8. Nígbà tí wọ́n dé Heburoni, wọ́n gbé orí rẹ̀ tọ Dafidi ọba lọ, wọ́n sì wí fún un pé, “Orí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ọ̀tá rẹ, tí ó ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ nìyí; oluwa mi, ọba, OLUWA ti mú kí ó ṣeéṣe láti gbẹ̀san, lára Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀.”

9. Ṣugbọn Dafidi dá wọn lóhùn pé, “OLUWA tí ó ti ń yọ mí ninu gbogbo ewu, ni mo fi búra pé,

Samuẹli Keji 4