Samuẹli Keji 21:10 BIBELI MIMỌ (BM)

Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru.

Samuẹli Keji 21

Samuẹli Keji 21:3-16