Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”