Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin.