Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bi í pé, “Kabiyesi, ọ̀rọ̀ yìí rú wa lójú, kí ni ohun tí ò ń ṣe yìí? Nígbà tí ọmọ yìí wà láàyè, ò ń gbààwẹ̀, ò ń sọkún nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gbàrà tí ó kú tán, o dìde o sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun!”