Samuẹli Keji 11:26-27 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Nígbà tí Batiṣeba gbọ́ pé wọ́n ti pa ọkọ òun, ó ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

27. Nígbà tí àkókò ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Dafidi ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin, Batiṣeba sì di aya rẹ̀. Ó bí ọmọkunrin kan fún un, ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí ohun tí Dafidi ṣe.

Samuẹli Keji 11