1. Lẹ́yìn èyí, ni Nahaṣi, ọba Amoni kú, Hanuni, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè.
2. Dafidi ọba wí pé, “N óo ṣe ẹ̀tọ́ fún Hanuni, ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe ẹ̀tọ́ fún mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú ninu, nítorí ikú baba rẹ̀.Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Dafidi dé Amoni,
3. àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.”
4. Hanuni bá ki àwọn oníṣẹ́ Dafidi mọ́lẹ̀, ó fá apá kan irùngbọ̀n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, ó gé aṣọ wọn ní déédé ìbàdí, ó sì tì wọ́n jáde.
5. Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀.