Sakaraya 9:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli.

2. Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

Sakaraya 9