Sakaraya 11:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanonikí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ!

2. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi,nítorí igi kedari ti ṣubú,àwọn igi ológo ti parun.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani,nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀!

3. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran,nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́.Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù,nítorí igbó tí wọn ń gbélẹ́bàá odò Jọdani ti parun!

4. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n.

5. Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.”

6. OLUWA ní, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n kò ní ṣàánú àwọn eniyan ilẹ̀ yìí mọ́. Fúnra mi ni n óo fi wọ́n lé àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba wọn lọ́wọ́. Wọn óo run ilẹ̀ náà, n kò sì ní gba ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ wọn.”

7. Mo ti di darandaran agbo ẹran tí à ń dà lọ fún àwọn alápatà. Mo mú ọ̀pá meji, mo sọ ọ̀kan ní “Oore-ọ̀fẹ́,” mo sì sọ ekeji ní “Ìṣọ̀kan.”

8. Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan.

9. Mo wá sọ fún àwọn agbo ẹran náà pé, “N kò ní ṣe olùṣọ́ yín mọ́. Èyí tí yóo bá kú ninu yín kí ó kú, èyí tí yóo bá ṣègbé, kí ó ṣègbé, kí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù sì máa pa ara wọn jẹ.”

Sakaraya 11