7. Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda.
8. Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run.
9. Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.
10. Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.”
11. Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó?
12. Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin,
13. ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.”
14. Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀.