1. Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé,
2. ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo.
3. Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà.
11-12. Ṣugbọn kí á tó bí àwọn ọmọ náà, àní sẹ́, kí wọ́n tó dá ohunkohun ṣe, yálà rere ni tabi burúkú, ni Ọlọrun ti sọ fún Rebeka pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo máa ṣe iranṣẹ àbúrò rẹ̀.” Báyìí ni Ọlọrun ti ń ṣe ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé, nígbà tí ó bá yan àwọn kan. Ó wá hàn kedere pé Ọlọrun kì í wo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan kí ó tó yàn wọ́n; àwọn tí ó bá pinnu tẹ́lẹ̀ láti yàn ní í pè.