7. Kí ni kí á wá wí wàyí ò? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Ṣugbọn ṣá, èmi kì bá tí mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí Òfin kò bá fi í hàn mí. Bí àpẹẹrẹ, ǹ bá tí mọ ojúkòkòrò bí Òfin kò bá sọ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.”
8. Àṣẹ yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ rí dìrọ̀ mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Ó ń fi èrò oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí mi lọ́kàn. Bí a bá mú òfin kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú.
9. Nígbà kan rí mò ń gbé ìgbésí-ayé mi láìsí òfin. Ṣugbọn nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ yọjú pẹlu,
10. ni mo bá kú. Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, ni ó wá di ọ̀ràn ikú fún mi.