3. Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn.
4. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere.
5. Tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí a ti ń ṣe ìfẹ́ inú wa bí ẹlẹ́ran-ara, èrò ọkàn wa a máa fà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin dá wa lẹ́kun rẹ̀, láti tì wá sí ohun tí àyọrísí rẹ̀ jẹ́ ikú.