9. Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10. Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé,“Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan.
11. Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun.
12. Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo wọn kò níláárí mọ́,kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.
13. Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn,ẹ̀tàn kún ẹnu wọn;oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn;
14. ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú.
15. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
16. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn.
17. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia.
18. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.”
19. A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun.
20. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀.
21. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i.
22. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan.
23. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun.
24. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe.
27. Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni.
28. Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́.
29. Àbí ti àwọn Juu nìkan ni Ọlọrun, kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù? Dájúdájú Ọlọrun àwọn Juu ati ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni.
30. Nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà, òun ni ó sì ń dá àwọn tí ó kọlà láre nípa igbagbọ, tí ó tún ń dá àwọn tí kò kọlà láre nípa igbagbọ bákan náà.