Romu 15:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi.

7. Nítorí náà, ẹ fa ara yín mọ́ra gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà yín, kí á lè fi ògo fún Ọlọrun.

8. Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ,

9. ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo kọrin sí orúkọ rẹ.”

10. Ó tún sọ pé,“Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.”

11. Ó tún sọ pé,“Ẹ yin Oluwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdèkí gbogbo eniyan yìn ín.”

12. Aisaya tún sọ pé,“Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ,yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè,nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.”

13. Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́.

Romu 15