7. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn.
8. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá.
9. Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè.
10. Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun!
11. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní,‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún,Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ”
12. Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun.