18. Ojú ọ̀run ti ṣí sílẹ̀, Ọlọrun sì ń tú ibinu rẹ̀ sórí gbogbo eniyan nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú tí wọn ń hù, tí wọ́n fi ń ṣe ìdènà fún òtítọ́.
19. Nítorí ohun tí eniyan lè mọ̀ nípa Ọlọrun ti hàn sí wọn, Ọlọrun ni ó ti fihàn wọ́n.
20. Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí.
21. Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn.
22. Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀.
23. Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò.
24. Nítorí náà Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn.
25. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin.
26. Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu.