Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí.