9. Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao.
10. Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.
11. A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà,tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ.
12. Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀,turari mi ń tú òórùn dídùn jáde.
13. Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá,bí ó ti sùn lé mi láyà.
14. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi,ninu ọgbà àjàrà Engedi.
15. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi;o lẹ́wà pupọ.Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà.
16. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi,o lẹ́wà gan-an ni.Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa.